Surah Al-Ahqaf — The Dunes
Surah Al-Ahqaf (The Dunes) is chapter 46 of the Quran, with 35 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
حمٓ
Hā mīm
Ayah 1تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Ayah 2مَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلࣲ مُّسَمࣰّ ىۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَمَّآ أُنذِرُواْ مُعۡرِضُونَ
A ò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn
Ayah 3قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكࣱ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِۖ ٱئۡتُونِي بِكِتَٰبࣲ مِّن قَبۡلِ هَٰذَآ أَوۡ أَثَٰرَةࣲ مِّنۡ عِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo
Ayah 4وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّن يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَن لَّا يَسۡتَجِيبُ لَهُۥٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَهُمۡ عَن دُعَآئِهِمۡ غَٰفِلُونَ
Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n
Ayah 5وَإِذَا حُشِرَ ٱلنَّاسُ كَانُواْ لَهُمۡ أَعۡدَآءࣰ وَكَانُواْ بِعِبَادَتِهِمۡ كَٰفِرِينَ
Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn
Ayah 6وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتࣲ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ هَٰذَا سِحۡرࣱ مُّبِينٌ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké áwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa sọ ìsọkúsọ sí òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: "Èyí ni idán pọ́nńbélé
Ayah 7أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ إِنِ ٱفۡتَرَيۡتُهُۥ فَلَا تَمۡلِكُونَ لِي مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِۚ كَفَىٰ بِهِۦ شَهِيدَۢا بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Sọ pé: "Tí mo bá hun ún fúnra mi, ẹ ò ní ìkápá kiní kan fún mi ní ọ̀dọ̀ Allāhu (níbi ìyà Rẹ̀). Òun ni Onímọ̀-jùlọ nípa ìsọkúsọ tí ẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀. Ó (sì) tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 8قُلۡ مَا كُنتُ بِدۡعࣰ ا مِّنَ ٱلرُّسُلِ وَمَآ أَدۡرِي مَا يُفۡعَلُ بِي وَلَا بِكُمۡۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ وَمَآ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرࣱ مُّبِينࣱ
Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé." wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lásìkò náà ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun t’ó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ni èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun (ahm.s.w.) tí kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn kristiẹni fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀. Bákan náà iṣẹ́ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ fáyé kò yàtọ̀ sí ti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (ahm.s.w). Bákan náà āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́
Ayah 9قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ وَكَفَرۡتُم بِهِۦ وَشَهِدَ شَاهِدࣱ مِّنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ عَلَىٰ مِثۡلِهِۦ فَـَٔامَنَ وَٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí
Ayah 10وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَوۡ كَانَ خَيۡرࣰ ا مَّا سَبَقُونَآ إِلَيۡهِۚ وَإِذۡ لَمۡ يَهۡتَدُواْ بِهِۦ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَآ إِفۡكࣱ قَدِيمࣱ
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān jẹ́ oore ni, wọn kò níí ṣíwájú wa débẹ̀." Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò ti tẹ̀lé ìmọ̀nà rẹ̀, ni wọ́n ń wí pé: "Irọ́ ijọ́un ni èyí
Ayah 11وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامࣰ ا وَرَحۡمَةࣰۚ وَهَٰذَا كِتَٰبࣱ مُّصَدِّقࣱ لِّسَانًا عَرَبِيࣰّ ا لِّيُنذِرَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُحۡسِنِينَ
Tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn. Al-Ƙur’ān) yìí tún ni Tírà kan t’ó ń jẹ́rìí sí òdodo ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn t’ó ṣàbòsí, (ó sì jẹ́) ìró ìdùnnú fún àwọn olùṣe-rere
Ayah 12إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa", lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, kò níí sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́
Ayah 13أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Ayah 14وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ إِحۡسَٰنًاۖ حَمَلَتۡهُ أُمُّهُۥ كُرۡهࣰ ا وَوَضَعَتۡهُ كُرۡهࣰ اۖ وَحَمۡلُهُۥ وَفِصَٰلُهُۥ ثَلَٰثُونَ شَهۡرًاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَبَلَغَ أَرۡبَعِينَ سَنَةࣰ قَالَ رَبِّ أَوۡزِعۡنِيٓ أَنۡ أَشۡكُرَ نِعۡمَتَكَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَٰلِدَيَّ وَأَنۡ أَعۡمَلَ صَٰلِحࣰ ا تَرۡضَىٰهُ وَأَصۡلِحۡ لِي فِي ذُرِّيَّتِيٓۖ إِنِّي تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَإِنِّي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí
Ayah 15أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنۡهُمۡ أَحۡسَنَ مَا عَمِلُواْ وَنَتَجَاوَزُ عَن سَيِّـَٔاتِهِمۡ فِيٓ أَصۡحَٰبِ ٱلۡجَنَّةِۖ وَعۡدَ ٱلصِّدۡقِ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn
Ayah 16وَٱلَّذِي قَالَ لِوَٰلِدَيۡهِ أُفࣲّ لَّكُمَآ أَتَعِدَانِنِيٓ أَنۡ أُخۡرَجَ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلۡقُرُونُ مِن قَبۡلِي وَهُمَا يَسۡتَغِيثَانِ ٱللَّهَ وَيۡلَكَ ءَامِنۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقࣱّ فَيَقُولُ مَا هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Ẹni tí ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì pé: "Ṣíọ̀ ẹ̀yin méjèèjì! Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣèlérí fún mi pé Wọn yóò mú mi jáde (láàyè láti inú sàréè), ṣebí àwọn ìran kan ti ré kọjá lọ ṣíwájú mi (tí Wọn kò tí ì mú wọn jáde láti inú sàréè wọn)." Àwọn (òbí rẹ̀) méjèèjì sì ń tọrọ ìgbàlà ní ọ̀dọ̀ Allāhu (fún ọmọ yìí. Wọ́n sì sọ pé): "Ègbé ni fún ọ! (O jẹ́) gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo." (Ọ̀mọ̀ náà sì) wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́
Ayah 17أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمࣲ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ
Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò
Ayah 18وَلِكُلࣲّ دَرَجَٰتࣱ مِّمَّا عَمِلُواْۖ وَلِيُوَفِّيَهُمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Àwọn ipò yóò wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Àti pé (èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Àwa kò sì níí ṣàbòsí sí wọn
Ayah 19وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَذۡهَبۡتُمۡ طَيِّبَٰتِكُمۡ فِي حَيَاتِكُمُ ٱلدُّنۡيَا وَٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهَا فَٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَسۡتَكۡبِرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَفۡسُقُونَ
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n máa sọ fún wọn pé:) "Ẹ ti lo ìgbádùn yín tán nínú ìṣẹ̀mí ayé? Ẹ sì ti jẹ ìgbádùn ayé? Nítorí náà, ní òní, wọ́n máa san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí pé ẹ̀ ń ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣèbàjẹ́
Ayah 20۞وَٱذۡكُرۡ أَخَا عَادٍ إِذۡ أَنذَرَ قَوۡمَهُۥ بِٱلۡأَحۡقَافِ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلنُّذُرُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦٓ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمࣲ
Ṣèrántí arákùnrin (ìjọ) ‘Ād. Nígbà tí ó ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ t’ó ń gbé nínú yanrìn tí atẹ́gùn kójọ bí òkè. Àwọn olùkìlọ̀ sì ti ré kọjá ṣíwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀. (Ó sì sọ pé:) "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá kan fun yín
Ayah 21قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِتَأۡفِكَنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Wọ́n wí pé: "Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo
Ayah 22قَالَ إِنَّمَا ٱلۡعِلۡمُ عِندَ ٱللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمࣰ ا تَجۡهَلُونَ
Ó sọ pé: "Ìmọ̀ (nípa rẹ̀) wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo. Èmi yó sì jẹ́ iṣẹ́ tí Wọ́n fi rán mi dé òpin fun yín, ṣùgbọ́n èmi ń ri ẹ̀yin ní ìjọ aláìmọ̀kan
Ayah 23فَلَمَّا رَأَوۡهُ عَارِضࣰ ا مُّسۡتَقۡبِلَ أَوۡدِيَتِهِمۡ قَالُواْ هَٰذَا عَارِضࣱ مُّمۡطِرُنَاۚ بَلۡ هُوَ مَا ٱسۡتَعۡجَلۡتُم بِهِۦۖ رِيحࣱ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمࣱ
Nígbà tí wọ́n rí ìyà náà ní ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, t’ó ń wọ́ bọ̀ wá sínú àwọn kòtò ìlú wọn, wọ́n wí pé: "Èyí ni ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tí ó máa rọ̀jò fún wa." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ni. Atẹ́gùn tí ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà nínú rẹ̀ ni
Ayah 24تُدَمِّرُ كُلَّ شَيۡءِۭ بِأَمۡرِ رَبِّهَا فَأَصۡبَحُواْ لَا يُرَىٰٓ إِلَّا مَسَٰكِنُهُمۡۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san
Ayah 25وَلَقَدۡ مَكَّنَّٰهُمۡ فِيمَآ إِن مَّكَّنَّٰكُمۡ فِيهِ وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ سَمۡعࣰ ا وَأَبۡصَٰرࣰ ا وَأَفۡـِٔدَةࣰ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُمۡ سَمۡعُهُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُهُمۡ وَلَآ أَفۡـِٔدَتُهُم مِّن شَيۡءٍ إِذۡ كَانُواْ يَجۡحَدُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
A kúkú fún wọn ní ipò tí A ò fún ẹ̀yin. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po
Ayah 26وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَا مَا حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡقُرَىٰ وَصَرَّفۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Àwa kúkú ti pa rẹ́ nínú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká yín. Àwa sì ti ṣàlàyé àwọn āyah náà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)
Ayah 27فَلَوۡلَا نَصَرَهُمُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ قُرۡبَانًا ءَالِهَةَۢۖ بَلۡ ضَلُّواْ عَنۡهُمۡۚ وَذَٰلِكَ إِفۡكُهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́
Ayah 28وَإِذۡ صَرَفۡنَآ إِلَيۡكَ نَفَرࣰ ا مِّنَ ٱلۡجِنِّ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوٓاْ أَنصِتُواْۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوۡاْ إِلَىٰ قَوۡمِهِم مُّنذِرِينَ
(Rántí) nígbà tí A darí ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú sí ọ, tí wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ al-Ƙur’ān. Nígbà tí wọ́n dé síbẹ̀, wọ́n sọ pé: "Ẹ dákẹ́ (fún al-Ƙur’ān)." Nígbà tí wọ́n sì parí (kíké rẹ̀ tán), wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ (fún wọn)
Ayah 29قَالُواْ يَٰقَوۡمَنَآ إِنَّا سَمِعۡنَا كِتَٰبًا أُنزِلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقࣰ ا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقࣲ مُّسۡتَقِيمࣲ
Wọ́n sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ wa, dájúdájú àwa gbọ́ (nípa) Tírà kan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn (Ànábì) Mūsā, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ni sí ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà tààrà
Ayah 30يَٰقَوۡمَنَآ أَجِيبُواْ دَاعِيَ ٱللَّهِ وَءَامِنُواْ بِهِۦ يَغۡفِرۡ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُجِرۡكُم مِّنۡ عَذَابٍ أَلِيمࣲ
Ẹ̀yin ìjọ wa, ẹ jẹ́ ìpè olùpèpè Allāhu. Kí ẹ sì gbà á gbọ́ ní òdodo. (Allāhu) yó sì forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa yọ yín kúrò nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro
Ayah 31وَمَن لَّا يُجِبۡ دَاعِيَ ٱللَّهِ فَلَيۡسَ بِمُعۡجِزࣲ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَيۡسَ لَهُۥ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءُۚ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلࣲ مُّبِينٍ
Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì jẹ́pè olùpèpè Allāhu, kò lè mórí bọ́ mọ́ (Allāhu) lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
Ayah 32أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَلَمۡ يَعۡيَ بِخَلۡقِهِنَّ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ قَدِيرࣱ
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí kò sì káàárẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá wọn, (ṣé kò) ní agbára láti sọ àwọn òkú di alààyè ni? Rárá, (Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Ayah 33وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَلَيۡسَ هَٰذَا بِٱلۡحَقِّۖ قَالُواْ بَلَىٰ وَرَبِّنَاۚ قَالَ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sórí Iná, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé:) "Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?" Wọn yóò wí pé: "Rárá, (òdodo ni) Olúwa wa." (Allāhu máa) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́
Ayah 34فَٱصۡبِرۡ كَمَا صَبَرَ أُوْلُواْ ٱلۡعَزۡمِ مِنَ ٱلرُّسُلِ وَلَا تَسۡتَعۡجِل لَّهُمۡۚ كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَ مَا يُوعَدُونَ لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا سَاعَةࣰ مِّن نَّهَارِۭۚ بَلَٰغࣱۚ فَهَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Al-Ƙur’ān yìí sì ni ìjíṣẹ́ dópin. Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́
Ayah 35