Surah Al-Hujuraat — The Inner Apartments
Surah Al-Hujuraat (The Inner Apartments) is chapter 49 of the Quran, with 18 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيِ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمࣱ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbawájú mọ́ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀
Ayah 1يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَرۡفَعُوٓاْ أَصۡوَٰتَكُمۡ فَوۡقَ صَوۡتِ ٱلنَّبِيِّ وَلَا تَجۡهَرُواْ لَهُۥ بِٱلۡقَوۡلِ كَجَهۡرِ بَعۡضِكُمۡ لِبَعۡضٍ أَن تَحۡبَطَ أَعۡمَٰلُكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura
Ayah 2إِنَّ ٱلَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصۡوَٰتَهُمۡ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱمۡتَحَنَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمۡ لِلتَّقۡوَىٰۚ لَهُم مَّغۡفِرَةࣱ وَأَجۡرٌ عَظِيمٌ
Dájúdájú àwọn t’ó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti gbìdánwò ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn
Ayah 3إِنَّ ٱلَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَآءِ ٱلۡحُجُرَٰتِ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ
Dájúdájú àwọn t’ó ń pè ọ́ láti ẹ̀yìn àwọn yàrá, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè
Ayah 4وَلَوۡ أَنَّهُمۡ صَبَرُواْ حَتَّىٰ تَخۡرُجَ إِلَيۡهِمۡ لَكَانَ خَيۡرࣰ ا لَّهُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورࣱ رَّحِيمࣱ
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n ṣe sùúrù títí o máa fi jáde sí wọn ni, ìbá dára jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 5يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن جَآءَكُمۡ فَاسِقُۢ بِنَبَإࣲ فَتَبَيَّنُوٓاْ أَن تُصِيبُواْ قَوۡمَۢا بِجَهَٰلَةࣲ فَتُصۡبِحُواْ عَلَىٰ مَا فَعَلۡتُمۡ نَٰدِمِينَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí òbìlẹ̀jẹ́ kan bá mú ìró kan wá ba yín, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti mọ òdodo (nípa ọ̀rọ̀ náà) nítorí kí ẹ má baà ṣe àwọn ènìyàn kan ní ṣùtá pẹ̀lú àìmọ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má baà di alábàámọ̀ lórí ohun tí ẹ ṣe
Ayah 6وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ فِيكُمۡ رَسُولَ ٱللَّهِۚ لَوۡ يُطِيعُكُمۡ فِي كَثِيرࣲ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ لَعَنِتُّمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِي قُلُوبِكُمۡ وَكَرَّهَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكُفۡرَ وَٱلۡفُسُوقَ وَٱلۡعِصۡيَانَۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّٰشِدُونَ
Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín. Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (t’ó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó o sínú ìdààmú. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà
Ayah 7فَضۡلࣰ ا مِّنَ ٱللَّهِ وَنِعۡمَةࣰۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمࣱ
(Èyí jẹ́) oore àjùlọ àti ìdẹ̀ra láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n
Ayah 8وَإِن طَآئِفَتَانِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱقۡتَتَلُواْ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَاۖ فَإِنۢ بَغَتۡ إِحۡدَىٰهُمَا عَلَى ٱلۡأُخۡرَىٰ فَقَٰتِلُواْ ٱلَّتِي تَبۡغِي حَتَّىٰ تَفِيٓءَ إِلَىٰٓ أَمۡرِ ٱللَّهِۚ فَإِن فَآءَتۡ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَا بِٱلۡعَدۡلِ وَأَقۡسِطُوٓاْۖ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ
Tí igun méjì nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo bá ń bá ara wọn jà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì bá sì kọjá ẹnu-àlà lórí ìkejì, ẹ bá èyí tí ó kọjá ẹnu-àlà jà títí ó fi máa ṣẹ́rí padà síbi àṣẹ Allāhu. Tí ó bá sì ṣẹ́rí padà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú déédé. Kí ẹ sì ṣe ẹ̀tọ́. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-ẹ̀tọ́
Ayah 9إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ إِخۡوَةࣱ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَ أَخَوَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ
Ọmọ ìyá (ẹ̀sìn) ni àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹ ṣàtúnṣe láààrin àwọn ọmọ ìyá yín méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí A lè kẹ yín
Ayah 10يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَسۡخَرۡ قَوۡمࣱ مِّن قَوۡمٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُونُواْ خَيۡرࣰ ا مِّنۡهُمۡ وَلَا نِسَآءࣱ مِّن نِّسَآءٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُنَّ خَيۡرࣰ ا مِّنۡهُنَّۖ وَلَا تَلۡمِزُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَلَا تَنَابَزُواْ بِٱلۡأَلۡقَٰبِۖ بِئۡسَ ٱلِٱسۡمُ ٱلۡفُسُوقُ بَعۡدَ ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن لَّمۡ يَتُبۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín lóríkì burúkú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn alábòsí
Ayah 11يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱجۡتَنِبُواْ كَثِيرࣰ ا مِّنَ ٱلظَّنِّ إِنَّ بَعۡضَ ٱلظَّنِّ إِثۡمࣱۖ وَلَا تَجَسَّسُواْ وَلَا يَغۡتَب بَّعۡضُكُم بَعۡضًاۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمۡ أَن يَأۡكُلَ لَحۡمَ أَخِيهِ مَيۡتࣰ ا فَكَرِهۡتُمُوهُۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ تَوَّابࣱ رَّحِيمࣱ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àròsọ. Dájúdájú apá kan àròsọ ni ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ t’ó ti kú ni? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 12يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّا خَلَقۡنَٰكُم مِّن ذَكَرࣲ وَأُنثَىٰ وَجَعَلۡنَٰكُمۡ شُعُوبࣰ ا وَقَبَآئِلَ لِتَعَارَفُوٓاْۚ إِنَّ أَكۡرَمَكُمۡ عِندَ ٱللَّهِ أَتۡقَىٰكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرࣱ
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán
Ayah 13۞قَالَتِ ٱلۡأَعۡرَابُ ءَامَنَّاۖ قُل لَّمۡ تُؤۡمِنُواْ وَلَٰكِن قُولُوٓاْ أَسۡلَمۡنَا وَلَمَّا يَدۡخُلِ ٱلۡإِيمَٰنُ فِي قُلُوبِكُمۡۖ وَإِن تُطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَا يَلِتۡكُم مِّنۡ أَعۡمَٰلِكُمۡ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورࣱ رَّحِيمٌ
Àwọn Lárúbáwá oko sọ pé: "A gbàgbọ́ ní òdodo." Sọ pé: "Ẹ̀yin kò gbàgbọ́ ní òdodo." Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé: "A gba ’Islām." níwọ̀n ìgbà tí ìgbàgbọ́ òdodo kò tí ì wọ’nú ọkàn yín. Tí ẹ bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) kò níí dín kiní kan kù fun yín nínú (ẹ̀san) àwọn iṣẹ́ yín. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 14إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ لَمۡ يَرۡتَابُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّٰدِقُونَ
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olódodo
Ayah 15قُلۡ أَتُعَلِّمُونَ ٱللَّهَ بِدِينِكُمۡ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمࣱ
Sọ pé: "Ṣé ẹ máa kọ́ Allāhu ní ẹ̀sìn yín ni?" Allāhu sì mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan
Ayah 16يَمُنُّونَ عَلَيۡكَ أَنۡ أَسۡلَمُواْۖ قُل لَّا تَمُنُّواْ عَلَيَّ إِسۡلَٰمَكُمۖ بَلِ ٱللَّهُ يَمُنُّ عَلَيۡكُمۡ أَنۡ هَدَىٰكُمۡ لِلۡإِيمَٰنِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Wọ́n ń ṣèrègún lórí rẹ pé wọ́n gba ’Islām. Sọ pé: "Ẹ má fi ’Islām yín ṣèrègún lórí mi.” Bẹ́ẹ̀ ni! Allāhu l’Ó máa ṣèrègún lórí yín pé Ó fi yín mọ̀nà síbi ìgbàgbọ́ òdodo tí ẹ bá jẹ́ olódodo
Ayah 17إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Dájúdájú Allāhu mọ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Ayah 18