Surah At-Taariq — The Morning Star
Surah At-Taariq (The Morning Star) is chapter 86 of the Quran, with 17 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ
(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ
Ayah 1وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ
Ayah 2ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ
Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni)
Ayah 3إِن كُلُّ نَفۡسࣲ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظࣱ
Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika)
Ayah 4فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀
Ayah 5خُلِقَ مِن مَّآءࣲ دَافِقࣲ
Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́
Ayah 6يَخۡرُجُ مِنۢ بَيۡنِ ٱلصُّلۡبِ وَٱلتَّرَآئِبِ
Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin
Ayah 7إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجۡعِهِۦ لَقَادِرࣱ
Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
Ayah 8يَوۡمَ تُبۡلَى ٱلسَّرَآئِرُ
ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́
Ayah 9فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةࣲ وَلَا نَاصِرࣲ
Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un
Ayah 10وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجۡعِ
Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún
Ayah 11وَٱلۡأَرۡضِ ذَاتِ ٱلصَّدۡعِ
Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso)
Ayah 12إِنَّهُۥ لَقَوۡلࣱ فَصۡلࣱ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́)
Ayah 13وَمَا هُوَ بِٱلۡهَزۡلِ
Kì í sì ṣe àwàdà
Ayah 14إِنَّهُمۡ يَكِيدُونَ كَيۡدࣰ ا
Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an
Ayah 15وَأَكِيدُ كَيۡدࣰ ا
Èmi náà sì ń déte gan-an
Ayah 16فَمَهِّلِ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَمۡهِلۡهُمۡ رُوَيۡدَۢا
Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀
Ayah 17