Surah At-Tahrim — The Prohibition
Surah At-Tahrim (The Prohibition) is chapter 66 of the Quran, with 12 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكَۖ تَبۡتَغِي مَرۡضَاتَ أَزۡوَٰجِكَۚ وَٱللَّهُ غَفُورࣱ رَّحِيمࣱ
Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 1قَدۡ فَرَضَ ٱللَّهُ لَكُمۡ تَحِلَّةَ أَيۡمَٰنِكُمۡۚ وَٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fun yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n
Ayah 2وَإِذۡ أَسَرَّ ٱلنَّبِيُّ إِلَىٰ بَعۡضِ أَزۡوَٰجِهِۦ حَدِيثࣰ ا فَلَمَّا نَبَّأَتۡ بِهِۦ وَأَظۡهَرَهُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ عَرَّفَ بَعۡضَهُۥ وَأَعۡرَضَ عَنۢ بَعۡضࣲۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِۦ قَالَتۡ مَنۡ أَنۢبَأَكَ هَٰذَاۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡخَبِيرُ
Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni t’ó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i). Ànábì sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: "O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí."). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: "Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?" (Ànábì) sọ pé: "Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà
Ayah 3إِن تَتُوبَآ إِلَى ٱللَّهِ فَقَدۡ صَغَتۡ قُلُوبُكُمَاۖ وَإِن تَظَٰهَرَا عَلَيۡهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ مَوۡلَىٰهُ وَجِبۡرِيلُ وَصَٰلِحُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ
Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (tún wà fún un)
Ayah 4عَسَىٰ رَبُّهُۥٓ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبۡدِلَهُۥٓ أَزۡوَٰجًا خَيۡرࣰ ا مِّنكُنَّ مُسۡلِمَٰتࣲ مُّؤۡمِنَٰتࣲ قَٰنِتَٰتࣲ تَٰٓئِبَٰتٍ عَٰبِدَٰتࣲ سَٰٓئِحَٰتࣲ ثَيِّبَٰتࣲ وَأَبۡكَارࣰ ا
Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ, àwọn olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ ní adélébọ̀ àti wúńdíá
Ayah 5يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَأَهۡلِيكُمۡ نَارࣰ ا وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلۡحِجَارَةُ عَلَيۡهَا مَلَٰٓئِكَةٌ غِلَاظࣱ شِدَادࣱ لَّا يَعۡصُونَ ٱللَّهَ مَآ أَمَرَهُمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika t’ó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn
Ayah 6يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَعۡتَذِرُواْ ٱلۡيَوۡمَۖ إِنَّمَا تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san
Ayah 7يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ تُوبُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ تَوۡبَةࣰ نَّصُوحًا عَسَىٰ رَبُّكُمۡ أَن يُكَفِّرَ عَنكُمۡ سَيِّـَٔاتِكُمۡ وَيُدۡخِلَكُمۡ جَنَّٰتࣲ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ يَوۡمَ لَا يُخۡزِي ٱللَّهُ ٱلنَّبِيَّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥۖ نُورُهُمۡ يَسۡعَىٰ بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَبِأَيۡمَٰنِهِمۡ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَتۡمِمۡ لَنَا نُورَنَا وَٱغۡفِرۡ لَنَآۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ قَدِيرࣱ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní ìronúpìwàdà òdodo. Ó ṣeé ṣe pé Olúwa yín máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fun yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí Allāhu kò níí dójú ti Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọn yóò sọ pé: "Olúwa wa, pé ìmọ́lẹ̀ wa fún wa, kí O sì foríjìn wá. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Ayah 8يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ جَٰهِدِ ٱلۡكُفَّارَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱغۡلُظۡ عَلَيۡهِمۡۚ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Ibùgbé wọn sì ni iná Jahanamọ. Ìkángun náà sì burú
Ayah 9ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلࣰ ا لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱمۡرَأَتَ نُوحࣲ وَٱمۡرَأَتَ لُوطࣲۖ كَانَتَا تَحۡتَ عَبۡدَيۡنِ مِنۡ عِبَادِنَا صَٰلِحَيۡنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمۡ يُغۡنِيَا عَنۡهُمَا مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـࣰٔ ا وَقِيلَ ٱدۡخُلَا ٱلنَّارَ مَعَ ٱلدَّٰخِلِينَ
Allāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: "Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná)
Ayah 10وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلࣰ ا لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱمۡرَأَتَ فِرۡعَوۡنَ إِذۡ قَالَتۡ رَبِّ ٱبۡنِ لِي عِندَكَ بَيۡتࣰ ا فِي ٱلۡجَنَّةِ وَنَجِّنِي مِن فِرۡعَوۡنَ وَعَمَلِهِۦ وَنَجِّنِي مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ
Allāhu tún fi ìyàwó Fir‘aon ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó gbàgbọ́. Nígbà tí ó sọ pé: "Olúwa mi, kọ́ ilé kan fún mi lọ́dọ̀ Rẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Là mí lọ́wọ́ Fir‘aon àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Kí O sì là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí
Ayah 11وَمَرۡيَمَ ٱبۡنَتَ عِمۡرَٰنَ ٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهِ مِن رُّوحِنَا وَصَدَّقَتۡ بِكَلِمَٰتِ رَبِّهَا وَكُتُبِهِۦ وَكَانَتۡ مِنَ ٱلۡقَٰنِتِينَ
Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu
Ayah 12