Surah Al-Hadid — The Iron
Surah Al-Hadid (The Iron) is chapter 57 of the Quran, with 29 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Ayah 1لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ قَدِيرٌ
TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Òun ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Ayah 2هُوَ ٱلۡأَوَّلُ وَٱلۡأٓخِرُ وَٱلظَّٰهِرُ وَٱلۡبَاطِنُۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ
Òun ni Àkọ́kọ́ àti Ìkẹ́yìn. Ó hàn (pẹ̀lú àmì bíbẹ Rẹ̀). Ó sì pamọ́ (fún gbogbo ojú nílé ayé). Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan
Ayah 3هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامࣲ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يَعۡلَمُ مَا يَلِجُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا يَخۡرُجُ مِنۡهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا يَعۡرُجُ فِيهَاۖ وَهُوَ مَعَكُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرࣱ
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan t’ó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan t’ó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Ayah 4لَّهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí
Ayah 5يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِۚ وَهُوَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Òun sì ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá
Ayah 6ءَامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَأَنفِقُواْ مِمَّا جَعَلَكُم مُّسۡتَخۡلَفِينَ فِيهِۖ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡ وَأَنفَقُواْ لَهُمۡ أَجۡرࣱ كَبِيرࣱ
Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kí ẹ sì ná nínú ohun tí Ó fi yín ṣe àrólé lórí rẹ̀. Nítorí náà, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì náwó (sí ojú ọ̀nà ẹ̀sìn), ẹ̀san t’ó tóbi wà fún wọn
Ayah 7وَمَا لَكُمۡ لَا تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلرَّسُولُ يَدۡعُوكُمۡ لِتُؤۡمِنُواْ بِرَبِّكُمۡ وَقَدۡ أَخَذَ مِيثَٰقَكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí gba Allāhu gbọ́ ní òdodo? Òjíṣẹ́ sì ń pè yín nítorí kí ẹ lè gba Olúwa yín gbọ́. Allāhu sì ti gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
Ayah 8هُوَ ٱلَّذِي يُنَزِّلُ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦٓ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتࣲ لِّيُخۡرِجَكُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ بِكُمۡ لَرَءُوفࣱ رَّحِيمࣱ
Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè mu yín kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fun yín
Ayah 9وَمَا لَكُمۡ أَلَّا تُنفِقُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلِلَّهِ مِيرَٰثُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَا يَسۡتَوِي مِنكُم مَّنۡ أَنفَقَ مِن قَبۡلِ ٱلۡفَتۡحِ وَقَٰتَلَۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَعۡظَمُ دَرَجَةࣰ مِّنَ ٱلَّذِينَ أَنفَقُواْ مِنۢ بَعۡدُ وَقَٰتَلُواْۚ وَكُلࣰّ ا وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرࣱ
Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí náwó fún ẹ̀sìn Allāhu? Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹni tí ó náwó ṣíwájú ṣíṣí ìlú Mọkkah, tí ó tún jagun ẹ̀sìn, kò dọ́gba láààrin yín (sí àwọn mìíràn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san wọn tóbi jùlọ sí ti àwọn t’ó náwó lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n tún jagun ẹ̀sìn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni Allāhu ṣ’àdéhùn ẹ̀san rere fún. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Ayah 10مَّن ذَا ٱلَّذِي يُقۡرِضُ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنࣰ ا فَيُضَٰعِفَهُۥ لَهُۥ وَلَهُۥٓ أَجۡرࣱ كَرِيمࣱ
Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, Ó sì máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún un. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì tún wà fún un
Ayah 11يَوۡمَ تَرَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ يَسۡعَىٰ نُورُهُم بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَبِأَيۡمَٰنِهِمۖ بُشۡرَىٰكُمُ ٱلۡيَوۡمَ جَنَّٰتࣱ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Ní ọjọ́ tí o máa rí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn níwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn, (A óò sọ pé:) "Ìró ìdùnnú yín ní òní ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀." Olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá
Ayah 12يَوۡمَ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتُ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱنظُرُونَا نَقۡتَبِسۡ مِن نُّورِكُمۡ قِيلَ ٱرۡجِعُواْ وَرَآءَكُمۡ فَٱلۡتَمِسُواْ نُورࣰ اۖ فَضُرِبَ بَيۡنَهُم بِسُورࣲ لَّهُۥ بَابُۢ بَاطِنُهُۥ فِيهِ ٱلرَّحۡمَةُ وَظَٰهِرُهُۥ مِن قِبَلِهِ ٱلۡعَذَابُ
Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín." A óò sọ fún wọn pé: "Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.” Wọ́n sì máa fi ògiri kan, t’ó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀, ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀
Ayah 13يُنَادُونَهُمۡ أَلَمۡ نَكُن مَّعَكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنَّكُمۡ فَتَنتُمۡ أَنفُسَكُمۡ وَتَرَبَّصۡتُمۡ وَٱرۡتَبۡتُمۡ وَغَرَّتۡكُمُ ٱلۡأَمَانِيُّ حَتَّىٰ جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ وَغَرَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ
(Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò pe (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) pé: "Ṣé àwa kò ti wà pẹ̀lú yín ni?" Wọ́n sọ pé: "Rárá, ṣùgbọ́n ẹ kó ìyọnu bá ẹ̀mí ara yín (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu), ẹ retí ìparun (wá), ẹ sì ṣiyèméjì (sí òdodo). Àwọn ìfẹ́-ọkàn àti irọ́ ọ̀rọ̀ sì tàn yín jẹ títí àṣẹ Allāhu fi dé. Àti pé (Èṣù) ẹlẹ́tàn sì tàn yín jẹ nípa Allāhu
Ayah 14فَٱلۡيَوۡمَ لَا يُؤۡخَذُ مِنكُمۡ فِدۡيَةࣱ وَلَا مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ مَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُۖ هِيَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Nítorí náà, ní òní Àwa kò níí gba ìtánràn kan ní ọwọ́ ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Iná ni ibùgbé yín. Òhun l’ó tọ́ si yín. Ìkángun náà sì burú
Ayah 15۞أَلَمۡ يَأۡنِ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَن تَخۡشَعَ قُلُوبُهُمۡ لِذِكۡرِ ٱللَّهِ وَمَا نَزَلَ مِنَ ٱلۡحَقِّ وَلَا يَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلُ فَطَالَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَمَدُ فَقَسَتۡ قُلُوبُهُمۡۖ وَكَثِيرࣱ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ
Ṣé àkókò kò tí ì tó fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí ọkàn wọn rọ̀ fún ìrántí Allāhu àti ohun t’ó sọ̀kalẹ̀ nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān). Kí wọ́n sì má ṣe dà bí àwọn tí A fún ní Tírà ní ìṣáájú; ìgbà pẹ́ lórí wọn, ọkàn wọn bá le. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́
Ayah 16ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ قَدۡ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah náá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè
Ayah 17إِنَّ ٱلۡمُصَّدِّقِينَ وَٱلۡمُصَّدِّقَٰتِ وَأَقۡرَضُواْ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنࣰ ا يُضَٰعَفُ لَهُمۡ وَلَهُمۡ أَجۡرࣱ كَرِيمࣱ
Dájúdájú àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, tí wọ́n tún yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, (Allāhu) yóò ṣàdìpèlé rẹ̀ fún wọn. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn
Ayah 18وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصِّدِّيقُونَۖ وَٱلشُّهَدَآءُ عِندَ رَبِّهِمۡ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ وَنُورُهُمۡۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ
Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo àti ẹlẹ́rìí ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ẹ̀san wọn àti ìmọ́lẹ̀ wọn wà fún wọn. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm
Ayah 19ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا لَعِبࣱ وَلَهۡوࣱ وَزِينَةࣱ وَتَفَاخُرُۢ بَيۡنَكُمۡ وَتَكَاثُرࣱ فِي ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَوۡلَٰدِۖ كَمَثَلِ غَيۡثٍ أَعۡجَبَ ٱلۡكُفَّارَ نَبَاتُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصۡفَرࣰّ ا ثُمَّ يَكُونُ حُطَٰمࣰ اۖ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابࣱ شَدِيدࣱ وَمَغۡفِرَةࣱ مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنࣱۚ وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا مَتَٰعُ ٱلۡغُرُورِ
Ẹ mọ̀ pé dájúdájú ìṣẹ̀mí ayé yìí jẹ́ eré, ìranù, ọ̀ṣọ́, ṣíṣe ìyanràn láààrin ara yín àti wíwá ọ̀pọ̀ dúkìá àti ọmọ. (Ìwọ̀nyí) dà bí òjò (t’ó mú irúgbìn jáde). Irúgbìn rẹ̀ sì ń jọ àwọn aláìgbàgbọ́ lójú. Lẹ́yìn náà, ó máa gbẹ. O sì máa rí i ní pípọ́n. Lẹ́yìn náà, ó máa di rírún (tí atẹ́gùn máa fẹ́ dànù). Ìyà líle àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu sì wà ní ọ̀run. Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn
Ayah 20سَابِقُوٓاْ إِلَىٰ مَغۡفِرَةࣲ مِّن رَّبِّكُمۡ وَجَنَّةٍ عَرۡضُهَا كَعَرۡضِ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ أُعِدَّتۡ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۚ ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ
Ẹ yára lọ síbi àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra tí fífẹ̀ rẹ̀ dà bí fífẹ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀. Wọ́n pa á lésè sílẹ̀ de àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu tí Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá
Ayah 21مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةࣲ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ إِلَّا فِي كِتَٰبࣲ مِّن قَبۡلِ أَن نَّبۡرَأَهَآۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرࣱ
Àdánwò kan kò níí ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ tàbí (kí ó ṣẹlẹ̀) sí ẹ̀yin àyàfi kí ó ti wà nínú Tírà ṣíwájú kí A t’ó dá ẹ̀dá. Dájúdájú ìyẹn rọ̀rùn fún Allāhu
Ayah 22لِّكَيۡلَا تَأۡسَوۡاْ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمۡ وَلَا تَفۡرَحُواْ بِمَآ ءَاتَىٰكُمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخۡتَالࣲ فَخُورٍ
(Ìṣẹ̀lẹ̀ ń tọ kádàrá lẹ́yìn) nítorí kí ẹ má ṣe banújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ fun yín àti nítorí kí ẹ má ṣe yọ àyọ̀jù lórí ohun tí Ó bá fun yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo onígbèéraga, onífáàrí
Ayah 23ٱلَّذِينَ يَبۡخَلُونَ وَيَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبُخۡلِۗ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
Àwọn t’ó ń ṣahun, tí wọ́n sì ń pa àwọn ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe (kí wọ́n mọ̀ pé) ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (tí kò náwó fún ẹ̀sìn), dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́
Ayah 24لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلَنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَنزَلۡنَا مَعَهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡمِيزَانَ لِيَقُومَ ٱلنَّاسُ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَأَنزَلۡنَا ٱلۡحَدِيدَ فِيهِ بَأۡسࣱ شَدِيدࣱ وَمَنَٰفِعُ لِلنَّاسِ وَلِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥ وَرُسُلَهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزࣱ
Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn àti òṣùwọ̀n nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). A tún sọ irin kalẹ̀. Ohun ìjagun t’ó lágbára àti àwọn àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni t’ó ń ran (ẹ̀sìn) Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí
Ayah 25وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحࣰ ا وَإِبۡرَٰهِيمَ وَجَعَلۡنَا فِي ذُرِّيَّتِهِمَا ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلۡكِتَٰبَۖ فَمِنۡهُم مُّهۡتَدࣲۖ وَكَثِيرࣱ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ
Dájúdájú A fi iṣẹ́ rán (Ànábì) Nūh àti (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. A fi ipò Ànábì sínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì pẹ̀lú Tírà (tí A fún wọn). Olùmọ̀nà wà nínú wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́
Ayah 26ثُمَّ قَفَّيۡنَا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم بِرُسُلِنَا وَقَفَّيۡنَا بِعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡإِنجِيلَۖ وَجَعَلۡنَا فِي قُلُوبِ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ رَأۡفَةࣰ وَرَحۡمَةࣰۚ وَرَهۡبَانِيَّةً ٱبۡتَدَعُوهَا مَا كَتَبۡنَٰهَا عَلَيۡهِمۡ إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ رِضۡوَٰنِ ٱللَّهِ فَمَا رَعَوۡهَا حَقَّ رِعَايَتِهَاۖ فَـَٔاتَيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنۡهُمۡ أَجۡرَهُمۡۖ وَكَثِيرࣱ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ
Lẹ́yìn náà, A fi àwọn Òjíṣẹ́ Wa tẹ̀lé orípa wọn. A sì mú ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé wọn. A fún un ni al-’Injīl. A fi àánú àti ìkẹ́ sínú ọkàn àwọn t’ó tẹ̀lé e. Àṣà àdáwà (láì lọ́kọ tàbí láì laya) wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀ ni. A ò ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí. (Wọn kò sì ṣe àdáwà fún kiní kan) bí kò ṣe láti fi wá ìyọ́nú Allāhu. Wọn kò sì rí i ṣọ́ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n ṣọ́ ọ. Nítorí náà, A fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú wọn ní ẹ̀san wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́
Ayah 27يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَءَامِنُواْ بِرَسُولِهِۦ يُؤۡتِكُمۡ كِفۡلَيۡنِ مِن رَّحۡمَتِهِۦ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ نُورࣰ ا تَمۡشُونَ بِهِۦ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورࣱ رَّحِيمࣱ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gba Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́ ní òdodo, nítorí kí (Allāhu) lè fun yín ní ìlọ́po méjì nínú ìkẹ́ Rẹ̀ àti nítorí kí Ó lè fun yín ní ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn àti nítorí kí Ó lè forí jìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Ayah 28لِّئَلَّا يَعۡلَمَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ أَلَّا يَقۡدِرُونَ عَلَىٰ شَيۡءࣲ مِّن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡفَضۡلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ
(Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ fun yín) nítorí kí àwọn ahlu-l-kitāb lè mọ̀ pé àwọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú oore àjùlọ Allāhu. Àti pé dájúdájú oore àjùlọ, ọwọ́ Allāhu l’ó wà. Ó sì ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá
Ayah 29