Surah Al-Ma'aarij — The Ascending Stairways

Surah Al-Ma'aarij (The Ascending Stairways) is chapter 70 of the Quran, with 44 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابࣲ وَاقِعࣲ‏

Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà t’ó máa ṣẹlẹ̀

Ayah 1

لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعࣱ‏

sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́

Ayah 2

مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ

lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga

Ayah 3

تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمࣲ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةࣲ‏

Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín)

Ayah 4

فَٱصۡبِرۡ صَبۡرࣰ ا جَمِيلًا

Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù t’ó rẹwà

Ayah 5

إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدࣰ ا

Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun t’ó jìnnà

Ayah 6

وَنَرَىٰهُ قَرِيبࣰ ا

A sì ń wò ó ní ohun t’ó súnmọ́

Ayah 7

يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ

(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí idẹ t’ó yọ́

Ayah 8

وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun

Ayah 9

وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمࣰ ا

ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀)

Ayah 10

يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ

Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn

Ayah 11

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ

Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀

Ayah 12

وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ

àti àwọn ẹbí rẹ̀ t’ó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé

Ayah 13

وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعࣰ ا ثُمَّ يُنجِيهِ

àti gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná)

Ayah 14

كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ

Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná t’ó ń jò fòfò)

Ayah 15

نَزَّاعَةࣰ لِّلشَّوَىٰ

Ó máa bó awọ orí tòró

Ayah 16

تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ

(Iná) yó máa ké sí ẹni t’ó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i

Ayah 17

وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ

ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn)

Ayah 18

۞إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا

Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà

Ayah 19

إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعࣰ ا

Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó

Ayah 20

وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا

Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì tẹ oore, ó máa yahun

Ayah 21

إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ

Àyàfi àwọn olùkírun

Ayah 22

ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ

àwọn olùdúnnímọ́ ìrun wọn

Ayah 23

وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقࣱّ مَّعۡلُومࣱ‏

àwọn t’ó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn

Ayah 24

لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ

sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún

Ayah 25

وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ

àwọn t’ó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo

Ayah 26

وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ

àwọn t’ó ń páyà ìyà Olúwa wọn

Ayah 27

إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونࣲ‏

dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí

Ayah 28

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ

àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn

Ayah 29

إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ

àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú

Ayah 30

فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ

nítorí náà, ẹni kẹ́ni t’ó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ-ẹnu àlà

Ayah 31

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ

àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn

Ayah 32

وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ

àwọn t’ó ń dúró ti ìjẹ́rìí wọn

Ayah 33

وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ

àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn

Ayah 34

أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتࣲ مُّكۡرَمُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

Ayah 35

فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ

Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ

Ayah 36

عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ

tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)

Ayah 37

أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيࣲٕ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمࣲ‏

Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni

Ayah 38

كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ

Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀

Ayah 39

فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ

Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára

Ayah 40

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرࣰ ا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ

láti lè fi àwọn t’ó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni t’ó lè kó agara bá Wa

Ayah 41

فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Ayah 42

يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعࣰ ا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبࣲ يُوفِضُونَ

Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan

Ayah 43

خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةࣱۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ

Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Ayah 44