Surah Al-A'laa — The Most High
Surah Al-A'laa (The Most High) is chapter 87 of the Quran, with 19 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى
Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ
Ayah 1ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ
Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba
Ayah 2وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ
Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà
Ayah 3وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ
Ẹni tí Ó mú koríko tútù (hù) jáde
Ayah 4فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ
Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ t’ó dúdú
Ayah 5سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ
Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé
Ayah 6إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ
Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun t’ó pamọ́
Ayah 7وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ
Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ
Ayah 8فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ
Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò
Ayah 9سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ
Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí
Ayah 10وَيَتَجَنَّبُهَا ٱلۡأَشۡقَى
Olórí-burúkú sì máa takété sí i
Ayah 11ٱلَّذِي يَصۡلَى ٱلنَّارَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná t’ó tóbi
Ayah 12ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ
Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà)
Ayah 13قَدۡ أَفۡلَحَ مَن تَزَكَّىٰ
Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn rẹ̀) ti jèrè
Ayah 14وَذَكَرَ ٱسۡمَ رَبِّهِۦ فَصَلَّىٰ
Ó tún rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun
Ayah 15بَلۡ تُؤۡثِرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé
Ayah 16وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرࣱ وَأَبۡقَىٰٓ
Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé
Ayah 17إِنَّ هَٰذَا لَفِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́
Ayah 18صُحُفِ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ
tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā
Ayah 19