Surah An-Naazi'aat — Those who drag forth

Surah An-Naazi'aat (Those who drag forth) is chapter 79 of the Quran, with 46 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.

وَٱلنَّٰزِعَٰتِ غَرۡقࣰ ا

Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́

Ayah 1

وَٱلنَّٰشِطَٰتِ نَشۡطࣰ ا

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo

Ayah 2

وَٱلسَّٰبِحَٰتِ سَبۡحࣰ ا

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀

Ayah 3

فَٱلسَّٰبِقَٰتِ سَبۡقࣰ ا

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà

Ayah 4

فَٱلۡمُدَبِّرَٰتِ أَمۡرࣰ ا

Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé

Ayah 5

يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ

Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe

Ayah 6

تَتۡبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ

Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e

Ayah 7

قُلُوبࣱ يَوۡمَئِذࣲ وَاجِفَةٌ

Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn

Ayah 8

أَبۡصَٰرُهَا خَٰشِعَةࣱ‏

Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ

Ayah 9

يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرۡدُودُونَ فِي ٱلۡحَافِرَةِ

Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)

Ayah 10

أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمࣰ ا نَّخِرَةࣰ‏

Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán

Ayah 11

قَالُواْ تِلۡكَ إِذࣰ ا كَرَّةٌ خَاسِرَةࣱ‏

Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́)

Ayah 12

فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةࣱ وَٰحِدَةࣱ‏

Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni

Ayah 13

فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ

Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa

Ayah 14

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

Ayah 15

إِذۡ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوًى

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā

Ayah 16

ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ

Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà

Ayah 17

فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ

Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí

Ayah 18

وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ

Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀)

Ayah 19

فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ

Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án

Ayah 20

فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ

(Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀

Ayah 21

ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ

Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó)

Ayah 22

فَحَشَرَ فَنَادَىٰ

Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì

Ayah 23

فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ

Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ

Ayah 24

فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ

Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́)

Ayah 25

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةࣰ لِّمَن يَخۡشَىٰٓ

Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu)

Ayah 26

ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا

Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ

Ayah 27

رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا

Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé

Ayah 28

وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا

Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde

Ayah 29

وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ

Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn

Ayah 30

أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا

Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀

Ayah 31

وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا

Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin

Ayah 32

مَتَٰعࣰ ا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ

Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín

Ayah 33

فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ

Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé

Ayah 34

يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ

ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́

Ayah 35

وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ

Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran

Ayah 36

فَأَمَّا مَن طَغَىٰ

Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà

Ayah 37

وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا

tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé

Ayah 38

فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ

dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)

Ayah 39

وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ

Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀)

Ayah 40

فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ

dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)

Ayah 41

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀

Ayah 42

فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ

Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná

Ayah 43

إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà

Ayah 44

إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا

Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀

Ayah 45

كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا

Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé)

Ayah 46