Surah Ash-Shams — The Sun
Surah Ash-Shams (The Sun) is chapter 91 of the Quran, with 15 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
وَٱلشَّمۡسِ وَضُحَىٰهَا
(Allāhu) búra pẹ̀lú òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀
Ayah 1وَٱلۡقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn)
Ayah 2وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru
Ayah 3وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀
Ayah 4وَٱلسَّمَآءِ وَمَا بَنَىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n
Ayah 5وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا طَحَىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀
Ayah 6وَنَفۡسࣲ وَمَا سَوَّىٰهَا
Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba
Ayah 7فَأَلۡهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقۡوَىٰهَا
Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n
Ayah 8قَدۡ أَفۡلَحَ مَن زَكَّىٰهَا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè
Ayah 9وَقَدۡ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù
Ayah 10كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِطَغۡوَىٰهَآ
Ìjọ Thamūd pe òdodo nírọ́ nípa ìtayọ ẹnu-àlà wọn
Ayah 11إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشۡقَىٰهَا
(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa)
Ayah 12فَقَالَ لَهُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقۡيَٰهَا
Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀)
Ayah 13فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمۡدَمَ عَلَيۡهِمۡ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمۡ فَسَوَّىٰهَا
Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn
Ayah 14وَلَا يَخَافُ عُقۡبَٰهَا
(Ẹni t’ó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn
Ayah 15