Surah Ad-Dhuhaa — The Morning Hours
Surah Ad-Dhuhaa (The Morning Hours) is chapter 93 of the Quran, with 11 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
وَٱلضُّحَىٰ
(Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta
Ayah 1وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ
Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú
Ayah 2مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ
Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ
Ayah 3وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرࣱ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ
Ayah 4وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ
Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i
Ayah 5أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمࣰ ا فَـَٔاوَىٰ
Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé
Ayah 6وَوَجَدَكَ ضَآلࣰّ ا فَهَدَىٰ
Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́
Ayah 7وَوَجَدَكَ عَآئِلࣰ ا فَأَغۡنَىٰ
Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀
Ayah 8فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ
Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí)
Ayah 9وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ
Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn)
Ayah 10وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ
Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde
Ayah 11