Surah Al-Mutaffifin — Defrauding
Surah Al-Mutaffifin (Defrauding) is chapter 83 of the Quran, with 36 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
وَيۡلࣱ لِّلۡمُطَفِّفِينَ
Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù
Ayah 1ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ
àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún
Ayah 2وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ
nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù
Ayah 3أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ
Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
Ayah 4لِيَوۡمٍ عَظِيمࣲ
ní Ọjọ́ ńlá kan
Ayah 5يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Ayah 6كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينࣲ
Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn
Ayah 7وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينࣱ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn
Ayah 8كِتَٰبࣱ مَّرۡقُومࣱ
Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn)
Ayah 9وَيۡلࣱ يَوۡمَئِذࣲ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́
Ayah 10ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́
Ayah 11وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ
Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀
Ayah 12إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)
Ayah 13كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn
Ayah 14كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذࣲ لَّمَحۡجُوبُونَ
Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn
Ayah 15ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm
Ayah 16ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́
Ayah 17كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ
Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn
Ayah 18وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn
Ayah 19كِتَٰبࣱ مَّرۡقُومࣱ
Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn)
Ayah 20يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ
Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i
Ayah 21إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ
Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn
Ayah 22عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn
Ayah 23تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ
Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn
Ayah 24يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقࣲ مَّخۡتُومٍ
Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí
Ayah 25خِتَٰمُهُۥ مِسۡكࣱۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ
Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn
Ayah 26وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ
Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà)
Ayah 27عَيۡنࣰ ا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ
(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu
Ayah 28إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ
Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín
Ayah 29وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ
Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́
Ayah 30وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí
Ayah 31وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà
Ayah 32وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ
Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn
Ayah 33فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ
Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín
Ayah 34عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn
Ayah 35هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ
Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)
Ayah 36