Surah At-Tin — The Fig
Surah At-Tin (The Fig) is chapter 95 of the Quran, with 8 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
وَٱلتِّينِ وَٱلزَّيۡتُونِ
Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn
Ayah 1وَطُورِ سِينِينَ
Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn
Ayah 2وَهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ٱلۡأَمِينِ
Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí
Ayah 3لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِيٓ أَحۡسَنِ تَقۡوِيمࣲ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ
Ayah 4ثُمَّ رَدَدۡنَٰهُ أَسۡفَلَ سَٰفِلِينَ
Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná)
Ayah 5إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونࣲ
Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn
Ayah 6فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعۡدُ بِٱلدِّينِ
Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)
Ayah 7أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَحۡكَمِ ٱلۡحَٰكِمِينَ
Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni
Ayah 8