Surah An-Naba — The Announcement
Surah An-Naba (The Announcement) is chapter 78 of the Quran, with 40 verses. This page presents the Arabic text with a Yoruba translation, verse by verse.
عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ
Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná
Ayah 1عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلۡعَظِيمِ
Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni
Ayah 2ٱلَّذِي هُمۡ فِيهِ مُخۡتَلِفُونَ
èyí tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
Ayah 3كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ
Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀
Ayah 4ثُمَّ كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ
Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀
Ayah 5أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ مِهَٰدࣰ ا
Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí
Ayah 6وَٱلۡجِبَالَ أَوۡتَادࣰ ا
àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)
Ayah 7وَخَلَقۡنَٰكُمۡ أَزۡوَٰجࣰ ا
A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo)
Ayah 8وَجَعَلۡنَا نَوۡمَكُمۡ سُبَاتࣰ ا
A ṣe oorun yín ní ìsinmi
Ayah 9وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ لِبَاسࣰ ا
A tún ṣe alẹ́ ní ìbora
Ayah 10وَجَعَلۡنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشࣰ ا
A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu
Ayah 11وَبَنَيۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعࣰ ا شِدَادࣰ ا
A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín
Ayah 12وَجَعَلۡنَا سِرَاجࣰ ا وَهَّاجࣰ ا
A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà
Ayah 13وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡمُعۡصِرَٰتِ مَآءࣰ ثَجَّاجࣰ ا
Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
Ayah 14لِّنُخۡرِجَ بِهِۦ حَبࣰّ ا وَنَبَاتࣰ ا
nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
Ayah 15وَجَنَّٰتٍ أَلۡفَافًا
pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko
Ayah 16إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ كَانَ مِيقَٰتࣰ ا
Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan
Ayah 17يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِ فَتَأۡتُونَ أَفۡوَاجࣰ ا
(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ
Ayah 18وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتۡ أَبۡوَٰبࣰ ا
Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn
Ayah 19وَسُيِّرَتِ ٱلۡجِبَالُ فَكَانَتۡ سَرَابًا
Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná
Ayah 20إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتۡ مِرۡصَادࣰ ا
Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà
Ayah 21لِّلطَّٰغِينَ مَـَٔابࣰ ا
(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ
Ayah 22لَّٰبِثِينَ فِيهَآ أَحۡقَابࣰ ا
Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ
Ayah 23لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرۡدࣰ ا وَلَا شَرَابًا
Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀
Ayah 24إِلَّا حَمِيمࣰ ا وَغَسَّاقࣰ ا
àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀
Ayah 25جَزَآءࣰ وِفَاقًا
(Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn)
Ayah 26إِنَّهُمۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ حِسَابࣰ ا
Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́
Ayah 27وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا كِذَّابࣰ ا
Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an
Ayah 28وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ كِتَٰبࣰ ا
Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan
Ayah 29فَذُوقُواْ فَلَن نَّزِيدَكُمۡ إِلَّا عَذَابًا
Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà
Ayah 30إِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ مَفَازًا
Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Ayah 31حَدَآئِقَ وَأَعۡنَٰبࣰ ا
Àwọn ọgbà àti èso àjàrà
Ayah 32وَكَوَاعِبَ أَتۡرَابࣰ ا
àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí
Ayah 33وَكَأۡسࣰ ا دِهَاقࣰ ا
àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn)
Ayah 34لَّا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوࣰ ا وَلَا كِذَّٰبࣰ ا
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀
Ayah 35جَزَآءࣰ مِّن رَّبِّكَ عَطَآءً حِسَابࣰ ا
(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn)
Ayah 36رَّبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا ٱلرَّحۡمَٰنِۖ لَا يَمۡلِكُونَ مِنۡهُ خِطَابࣰ ا
(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀
Ayah 37يَوۡمَ يَقُومُ ٱلرُّوحُ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ صَفࣰّ اۖ لَّا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنۡ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَقَالَ صَوَابࣰ ا
Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú
Ayah 38ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلۡحَقُّۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ مَـَٔابًا
Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà)
Ayah 39إِنَّآ أَنذَرۡنَٰكُمۡ عَذَابࣰ ا قَرِيبࣰ ا يَوۡمَ يَنظُرُ ٱلۡمَرۡءُ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُ وَيَقُولُ ٱلۡكَافِرُ يَٰلَيۡتَنِي كُنتُ تُرَٰبَۢا
Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)
Ayah 40